Native Bible

3 John 1:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi kọ̀wé sí ìjọ ṣùgbọ́n Diotirefe, ẹni tí ó fẹ́ láti jẹ́ ẹni pàtàkì jùlọ, kò gbà wá.

3 John 1:9 in English

3 John 1:9 · Berean Standard Bible

I have written to the church about this,* but Diotrephes, who loves to be first, will not accept our instruction.

Context

7Nítorí pé, nítorí iṣẹ́ Kristi ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgba ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn aláìkọlà. 8Nítorí náà, ó yẹ kí àwa fi inú rere gba irú àwọn wọ̀nyí, kí àwa lè jẹ́ alábáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú òtítọ́. 9Èmi kọ̀wé sí ìjọ ṣùgbọ́n Diotirefe, ẹni tí ó fẹ́ láti jẹ́ ẹni pàtàkì jùlọ, kò gbà wá. 10Nítorí náà bí mo bá dé, èmi yóò mú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ṣe wá sì ìrántí rẹ, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ búburú àti ìsọkúsọ sí wa, èyí kò sì tún tẹ́ ẹ lọ́rùn, síbẹ̀ òun fúnra rẹ̀ kọ̀ láti gba àwọn ará, àwọn tí ó sì ń fẹ́ gbà wọ́n, ó ń dá wọn lẹ́kun, ó sì ń lé wọn kúrò nínú ìjọ. 11Olùfẹ́, má ṣe ṣe àfarawé ohun tí í ṣe ibi bí kò ṣe ohun tí ṣe rere. Ẹni tí ó bá ń ṣe rere ti Ọlọ́run ni; ẹni tí ó ba ń ṣe búburú kò rí Ọlọ́run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.