2 Timotiu 4:11
2 Timothy 4:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Luku nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Marku wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́.
2 Timothy 4:11 in English
2 Timothy 4:11 · Berean Standard Bible
Only Luke is with me. Get Mark and bring him with you, because he is useful to me in the ministry.
Context
9Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá. 10Nítorí Dema ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalonika; Kreskeni sí Galatia, Titu sí Dalimatia. 11Luku nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Marku wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́. 12Mo rán Tikiku ní iṣẹ́ lọ sí Efesu. 13Aṣọ òtútù tí mo fi sílẹ̀ ní Troasi lọ́dọ̀ Karpu, nígbà tí ìwọ bá ń bọ̀ mú un wa, àti àwọn ìwé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìwé-awọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.