Native Bible

2 Timothy 1:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa nínú Kristi Jesu láti ìpìlẹ̀ ayérayé,

2 Timothy 1:9 in English

2 Timothy 1:9 · Berean Standard Bible

He has saved us and called us to a holy calling, not because of our works, but by His own purpose and by the grace He granted us in Christ Jesus before time began.*

Context

7Nítorí pé Ọlọ́run kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ìsẹ́ra-ẹni ti ó yè kooro. 8Nítorí náà, má ṣe tijú láti jẹ́rìí nípa Olúwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀; ṣùgbọ́n kí ìwọ ṣe alábápín nínú ìpọ́njú ìyìnrere nípa agbára Ọlọ́run, 9ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa nínú Kristi Jesu láti ìpìlẹ̀ ayérayé, 10ṣùgbọ́n tí a fihàn nísinsin yìí nípa ìfarahàn Jesu Kristi Olùgbàlà wa, ẹni ti ó pa ikú run, tí ó sì mú ìyè àti àìkú wá sí ìmọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ìyìnrere. 11Fún ti ìyìnrere tí a yàn mi láti jẹ oníwàásù àti aposteli àti olùkọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.