Native Bible

2 Timothy 1:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Sí Timotiu, ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n: Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Kristi Jesu Olúwa wa.

2 Timothy 1:2 in English

2 Timothy 1:2 · Berean Standard Bible

To Timothy, my beloved child: Grace, mercy, and peace from God the Father and Christ Jesus our Lord.

Context

1Paulu, aposteli ti Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè ti ń bẹ nínú Kristi Jesu, 2Sí Timotiu, ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n: Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Kristi Jesu Olúwa wa. 3Mo dá ọpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí èmi ń sìn pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba mi ti í ṣe, pé ni àìsimi lọ́sàn án àti lóru ni mo ń ṣe ìrántí rẹ nínú àdúrà mi. 4Bí mo ti rántí omijé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni mo ń fẹ́ láti rí ọ kí èmi kí ó lè kún fún ayọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.