2 Timotiu 1:12
2 Timothy 1:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí, nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà.
2 Timothy 1:12 in English
2 Timothy 1:12 · Berean Standard Bible
For this reason, even though I suffer as I do, I am not ashamed; for I know whom I have believed, and I am convinced that He is able to guard what I have entrusted to Him * for that day.
Context
10ṣùgbọ́n tí a fihàn nísinsin yìí nípa ìfarahàn Jesu Kristi Olùgbàlà wa, ẹni ti ó pa ikú run, tí ó sì mú ìyè àti àìkú wá sí ìmọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ìyìnrere. 11Fún ti ìyìnrere tí a yàn mi láti jẹ oníwàásù àti aposteli àti olùkọ́. 12Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí, nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà. 13Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kristi Jesu. 14Pa ohun rere ti a ti fi lé ọ lọ́wọ́ mọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ń gbé inú wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.