2 Tẹsalonika 2:6
2 Thessalonians 2:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti pé nísinsin yìí, ẹ̀yin mọ ohun tí ń dá a dúró, kí a bá a lè fi í hàn ní àkókò rẹ̀ gan an.
2 Thessalonians 2:6 in English
2 Thessalonians 2:6 · Berean Standard Bible
And you know what is now restraining him, so that he may be revealed at the proper time.
Context
4Òun yóò lòdì sí, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga sí gbogbo ohun tí a ń pè ní Ọlọ́run tàbí tí a ń sìn, dé ibi pé yóò gbé ara rẹ̀ jókòó nínú tẹmpili Ọlọ́run, tí yóò sì pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run. 5Ṣé ẹ̀yin kò rántí pé nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín, mo ń sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún un yín. 6Àti pé nísinsin yìí, ẹ̀yin mọ ohun tí ń dá a dúró, kí a bá a lè fi í hàn ní àkókò rẹ̀ gan an. 7Nítorí agbára ìkọ̀kọ̀ ẹni ẹ̀ṣẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ń dènà yóò máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí a ó fi mú un kúrò ní ọ̀nà. 8Nígbà náà ni a ó fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, ẹni tí Jesu Olúwa yóò fi èémí ẹnu rẹ̀ pa, tí yóò sì fi ọlá ìpadàbọ̀ rẹ̀ parun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.