Native Bible

2 Thessalonians 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

kí wọn kí ó lè gba ìdálẹ́bi, àní àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ní inú dídùn nínú ìwà búburú.

2 Thessalonians 2:12 in English

2 Thessalonians 2:12 · Berean Standard Bible

in order that judgment may come upon all who have disbelieved the truth and delighted in wickedness.

Context

10ní gbogbo ọ̀nà búburú tí a fi ń tan àwọn tí ń ṣègbé jẹ. Wọ́n ṣègbé nítorí wọ́n kọ̀ láti fẹ́ràn òtítọ́ kí wọn sì di ẹni ìgbàlà. 11Nítorí ìdí èyí, Ọlọ́run rán ohun tó ń ṣiṣẹ́ ìṣìnà sí wọn kí wọn lè gba èké gbọ́, 12kí wọn kí ó lè gba ìdálẹ́bi, àní àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ní inú dídùn nínú ìwà búburú. 13Ṣùgbọ́n, ohun tí ó tọ́ fún wa ni láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará olùfẹ́ ní ti Olúwa, nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn yín sí ìgbàlà nípa ìsọdimímọ́ ti Ẹ̀mí àti nípa gbígba òtítọ́ gbọ́. 14Òun ti pè yín sí èyí nípa ìyìnrere wa, kí ẹ̀yin kí ó lè pín nínú ògo Jesu Kristi Olúwa wa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.