2 Tẹsalonika 1:6
2 Thessalonians 1:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú,
2 Thessalonians 1:6 in English
2 Thessalonians 1:6 · Berean Standard Bible
After all, it is only right for God to repay with affliction those who afflict you,
Context
4Nítorí náà, àwa tìkára wa ń fi yín ṣògo nínú ìjọ Ọlọ́run, nítorí sùúrù àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà. 5Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé òdodo ni ìdájọ́ Ọlọ́run àti pé nítorí èyí ni a ó kà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, nítorí èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe ń jìyà. 6Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú, 7Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì ṣe nígbà ìfarahàn Jesu Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn angẹli alágbára. 8Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìyìnrere Jesu Olúwa wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.