Native Bible

2 Samuel 7:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Àti kín ní ó tún kù tí Dafidi ìbá tún máa wí fún ọ? Ìwọ, Olúwa Olódùmarè mọ̀ ìránṣẹ́ rẹ.

2 Samuel 7:20 in English

2 Samuel 7:20 · Berean Standard Bible

What more can David say to You? For You know Your servant, O Lord GOD.

Context

18Dafidi ọba sì wọlé lọ, ó sì dúró níwájú Olúwa, ó sì wí pé, “Olúwa Olódùmarè, ta ni èmi, àti kí sì ni ìdílé mi, tí ìwọ fi mú mi di ìsinsin yìí? 19Nǹkan kékeré ni èyí sá à jásí lójú rẹ, Olúwa Olódùmarè; ìwọ sì ti sọ nípa ìdílé ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀lú ní ti àkókò tí o jìnnà. Èyí ha ṣe ìwà ènìyàn bí, Olúwa Olódùmarè? 20“Àti kín ní ó tún kù tí Dafidi ìbá tún máa wí fún ọ? Ìwọ, Olúwa Olódùmarè mọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. 21Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni ìwọ ṣe ṣe gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí, kí ìránṣẹ́ rẹ lè mọ̀. 22“Ìwọ sì tóbi, Olúwa Olódùmarè! Kò sì sí ẹni tí ó dàbí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan lẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí àwa fi etí wá gbọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.