2 Samuẹli 7:17
2 Samuel 7:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìran yìí, bẹ́ẹ̀ ni Natani sì sọ fún Dafidi.
2 Samuel 7:17 in English
2 Samuel 7:17 · Berean Standard Bible
So Nathan relayed to David all the words of this entire vision.
Context
15Ṣùgbọ́n àánú mi kì yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú un kúrò lọ́dọ̀ Saulu, tí èmi ti mú kúrò níwájú rẹ. 16A ó sì fi ìdílé rẹ àti ìjọba rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ títí láé, a ó sì fi ìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ títí láé.’ ” 17Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìran yìí, bẹ́ẹ̀ ni Natani sì sọ fún Dafidi. 18Dafidi ọba sì wọlé lọ, ó sì dúró níwájú Olúwa, ó sì wí pé,
“Olúwa Olódùmarè, ta ni èmi, àti kí sì ni ìdílé mi, tí ìwọ fi mú mi di ìsinsin yìí? 19Nǹkan kékeré ni èyí sá à jásí lójú rẹ, Olúwa Olódùmarè; ìwọ sì ti sọ nípa ìdílé ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀lú ní ti àkókò tí o jìnnà. Èyí ha ṣe ìwà ènìyàn bí, Olúwa Olódùmarè?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.