2 Samuẹli 6:22
2 Samuel 6:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìníyìn lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo.”
2 Samuel 6:22 in English
2 Samuel 6:22 · Berean Standard Bible
and I will humiliate and humble myself even more than this. Yet I will be honored by the maidservants of whom you have spoken.”
Context
20Dafidi sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Mikali ọmọbìnrin Saulu sì jáde láti wá pàdé Dafidi, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Israẹli ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.” 21Dafidi sì wí fún Mikali pé, “Níwájú Olúwa ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn Olúwa, àní lórí Israẹli, èmi ó sì súre níwájú Olúwa. 22Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìníyìn lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo.” 23Mikali ọmọbìnrin Saulu kò sì bí ọmọ, títí o fi di ọjọ́ ikú rẹ̀ nítorí tí ó sọ̀rọ̀-òdì yìí sí Dafidi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.