2 Samuẹli 5:13
2 Samuel 5:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì tún mú àwọn àlè àti aya sí i láti Jerusalẹmu wá, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti Hebroni bọ̀, wọ́n sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin fún Dafidi.
2 Samuel 5:13 in English
2 Samuel 5:13 · Berean Standard Bible
After he had arrived from Hebron, David took more concubines and wives from Jerusalem, and more sons and daughters were born to him.
Context
11Hiramu ọba Tire sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dafidi, àti igi kedari, àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn tí ń gbẹ́ òkúta, wọ́n kọ́ ilé kan fún Dafidi. 12Dafidi sì kíyèsi i pé, Olúwa ti fi ìdí òun múlẹ̀ láti jẹ ọba lórí Israẹli, àti pé, ó gbé ìjọba rẹ̀ ga nítorí Israẹli àwọn ènìyàn rẹ̀. 13Dafidi sì tún mú àwọn àlè àti aya sí i láti Jerusalẹmu wá, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti Hebroni bọ̀, wọ́n sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin fún Dafidi. 14Èyí sì ni orúkọ àwọn tí a bí fún un ní Jerusalẹmu; Ṣammua, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. 15Àti Ibhari, àti Eliṣua, àti Nefegi, àti Jafia.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.