2 Samuẹli 3:12
2 Samuel 3:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Abneri sì rán àwọn oníṣẹ́ sí Dafidi nítorí rẹ̀ wí pé, “Ti ta ni ilẹ̀ náà ń ṣe? Bá mi ṣe àdéhùn, èmi yóò si kó gbogbo Israẹli tọ̀ ọ́ wá.”
2 Samuel 3:12 in English
2 Samuel 3:12 · Berean Standard Bible
Then Abner sent messengers in his place to say to David, “To whom does the land belong? Make your covenant with me, and surely my hand will be with you to bring all Israel over to you.”
Context
10Láti mú ìjọba náà kúrò ní ìdílé Saulu, àti láti gbé ìtẹ́ Dafidi kalẹ̀ lórí Israẹli, àti lórí Juda, láti Dani títí ó fi dé Beerṣeba.” 11Òun kò sì lè dá Abneri lóhùn kan nítorí tí ó bẹ̀rù rẹ̀. 12Abneri sì rán àwọn oníṣẹ́ sí Dafidi nítorí rẹ̀ wí pé, “Ti ta ni ilẹ̀ náà ń ṣe? Bá mi ṣe àdéhùn, èmi yóò si kó gbogbo Israẹli tọ̀ ọ́ wá.” 13Òun sì wí pé, “Ó dára, èmi ó bá ọ ṣe àdéhùn, ṣùgbọ́n ohun kan ni èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, èyí ni pé, ìwọ kì yóò rí ojú mi, àfi bí ìwọ bá kọ́ mú Mikali ọmọbìnrin Saulu wá, nígbà tí ìwọ bá wá, láti rí ojú mi.” 14Dafidi sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Iṣboṣeti ọmọ Saulu pé, “Fi Mikali obìnrin mi lé mi lọ́wọ́, ẹni tí èmi ti fi ọgọ́rùn-ún awọ iwájú orí àwọn Filistini fẹ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.