Native Bible

2 Samuel 24:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì wá sí Gileadi, àti sí ilé Tatimi Hodṣi; wọ́n sì wá sí Dani Jaani àti yíkákiri sí Sidoni.

2 Samuel 24:6 in English

2 Samuel 24:6 · Berean Standard Bible

Then they went to Gilead and the land of Tahtim-hodshi,* and on to Dan-jaan and around to Sidon.

Context

4Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí ti Joabu, àti ti àwọn olórí ogun. Joabu àti àwọn olórí ogun sì jáde lọ kúrò níwájú ọba, láti lọ ka àwọn ènìyàn Israẹli. 5Wọ́n sì kọjá odò Jordani, wọ́n sì pàgọ́ ní Aroeri, ní ìhà apá ọ̀tún ìlú tí ó wà láàrín àfonífojì Gadi, àti sí ìhà Jaseri. 6Wọ́n sì wá sí Gileadi, àti sí ilé Tatimi Hodṣi; wọ́n sì wá sí Dani Jaani àti yíkákiri sí Sidoni. 7Wọ́n sì wá sí ìlú olódi Tire, àti sí gbogbo ìlú àwọn Hifi, àti ti àwọn ará Kenaani, wọ́n sì jáde lọ síhà gúúsù ti Juda, àní sí Beerṣeba. 8Wọ́n sì la gbogbo ilẹ̀ náà já, wọ́n sì wá sí Jerusalẹmu ní òpin oṣù kẹsànán àti ogúnjọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.