2 Samuẹli 24:5
2 Samuel 24:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì kọjá odò Jordani, wọ́n sì pàgọ́ ní Aroeri, ní ìhà apá ọ̀tún ìlú tí ó wà láàrín àfonífojì Gadi, àti sí ìhà Jaseri.
2 Samuel 24:5 in English
2 Samuel 24:5 · Berean Standard Bible
They crossed the Jordan and camped near Aroer, south of the town in the middle of the valley, and proceeded toward Gad and Jazer.
Context
3Joabu sì wí fún ọba pé, “Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi kún iye àwọn ènìyàn náà, iyekíye tí ó wù kí wọn jẹ́, ní ọ̀rọ̀ọ̀rún, ojú olúwa mi ọba yóò sì rí i, ṣùgbọ́n èétiṣe tí olúwa mi ọba fi fẹ́ nǹkan yìí?” 4Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí ti Joabu, àti ti àwọn olórí ogun. Joabu àti àwọn olórí ogun sì jáde lọ kúrò níwájú ọba, láti lọ ka àwọn ènìyàn Israẹli. 5Wọ́n sì kọjá odò Jordani, wọ́n sì pàgọ́ ní Aroeri, ní ìhà apá ọ̀tún ìlú tí ó wà láàrín àfonífojì Gadi, àti sí ìhà Jaseri. 6Wọ́n sì wá sí Gileadi, àti sí ilé Tatimi Hodṣi; wọ́n sì wá sí Dani Jaani àti yíkákiri sí Sidoni. 7Wọ́n sì wá sí ìlú olódi Tire, àti sí gbogbo ìlú àwọn Hifi, àti ti àwọn ará Kenaani, wọ́n sì jáde lọ síhà gúúsù ti Juda, àní sí Beerṣeba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.