2 Samuẹli 22:44
2 Samuel 22:44 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi, ìwọ pa mi mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn tí èmi kò tí mọ̀ yóò máa sìn mí.
2 Samuel 22:44 in English
2 Samuel 22:44 · Berean Standard Bible
You have delivered me from the strife of my people; You have preserved me as the head of nations; a people I had not known shall serve me.
Context
42Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n;
wọ́n wo Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá àwọn lóhùn. 43Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,
èmi sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ìta, èmi sì tẹ́ wọn gbọrọ. 44“Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi,
ìwọ pa mi mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè.
Àwọn ènìyàn tí èmi kò tí mọ̀ yóò máa sìn mí. 45Àwọn àjèjì wá láti tẹríba fún mi;
bí wọ́n bá ti gbúròó mi, wọ́n á sì gbọ́ tèmi. 46Àyà yóò pá àwọn àlejò,
wọ́n ó sì fi ìbẹ̀rù sá kúrò níbi kọ́lọ́fín wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.