2 Samuẹli 22:16
2 Samuel 22:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìṣàn ibú òkun sì fi ara hàn, ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn, nípa ìbáwí Olúwa, nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀.
2 Samuel 22:16 in English
2 Samuel 22:16 · Berean Standard Bible
The channels of the sea appeared, and the foundations of the world were exposed at the rebuke of the LORD, at the blast of the breath of His nostrils.
Context
14Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá,
Ọ̀gá-ògo jùlọ sì fọhùn rẹ̀. 15Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká;
ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn. 16Ìṣàn ibú òkun sì fi ara hàn,
ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn,
nípa ìbáwí Olúwa,
nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀. 17“Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi;
ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá. 18Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,
lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi, nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.