2 Samuẹli 2:31
2 Samuel 2:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì pa nínú àwọn ènìyàn Benjamini: nínú àwọn ọmọkùnrin Abneri; òjìdínnírinwó (360) ènìyàn.
2 Samuel 2:31 in English
2 Samuel 2:31 · Berean Standard Bible
but they had struck down 360 Benjamites who were with Abner.
Context
29Abneri àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì fi gbogbo òru náà rìn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì rìn ní gbogbo Bitironi, wọ́n sì wá sí Mahanaimu. 30Joabu sì dẹ́kun àti máa tọ Abneri lẹ́yìn: ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ, ènìyàn mọ́kàndínlógún ni ó kú pẹ̀lú Asaheli nínú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi. 31Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì pa nínú àwọn ènìyàn Benjamini: nínú àwọn ọmọkùnrin Abneri; òjìdínnírinwó (360) ènìyàn. 32Wọ́n si gbé Asaheli wọ́n sì sin ín sínú ibojì baba rẹ̀ tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu. Joabu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fi gbogbo òru náà rìn, ilẹ̀ sì mọ́ wọn sí Hebroni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.