Native Bible

2 Samuel 2:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Joabu sì fọ́n ìpè, gbogbo ènìyàn sì dúró jẹ́ẹ́, wọn kò sì lépa Israẹli mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì tún jà mọ́.

2 Samuel 2:28 in English

2 Samuel 2:28 · Berean Standard Bible

So Joab blew the ram’s horn, and all the troops stopped; they no longer pursued Israel or continued to fight.

Context

26Abneri sì pe Joabu, ó sì bi í léèrè pé, “Idà yóò máa parun títí láéláé bí? Ǹjẹ́ ìwọ kò ì tí ì mọ̀ pé yóò korò níkẹyìn? Ǹjẹ́ yóò ha ti pẹ́ tó kí ìwọ tó sọ fún àwọn ènìyàn náà, kí wọ́n dẹ́kun láti máa lépa arákùnrin wọn.” 27Joabu sì wí pé, “Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, bí kò ṣe bí ìwọ ti wí, nítòótọ́ ní òwúrọ̀ ni àwọn ènìyàn náà ìbá padà lẹ́yìn arákùnrin wọn.” 28Joabu sì fọ́n ìpè, gbogbo ènìyàn sì dúró jẹ́ẹ́, wọn kò sì lépa Israẹli mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì tún jà mọ́. 29Abneri àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì fi gbogbo òru náà rìn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì rìn ní gbogbo Bitironi, wọ́n sì wá sí Mahanaimu. 30Joabu sì dẹ́kun àti máa tọ Abneri lẹ́yìn: ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ, ènìyàn mọ́kàndínlógún ni ó kú pẹ̀lú Asaheli nínú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.