Native Bible

2 Samuel 19:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìránṣẹ́ rẹ yóò sì sin ọba lọ díẹ̀ gòkè odò Jordani; èéṣì ṣe tí ọba yóò fi san ẹ̀san yìí fún mi.

2 Samuel 19:36 in English

2 Samuel 19:36 · Berean Standard Bible

Your servant could go with the king only a short distance past the Jordan; why should the king repay me with such a reward?

Context

34Barsillai sì wí fún ọba pé, “Ọjọ́ mélòó ni ọdún ẹ̀mí mi kù, tí èmi ó fi bá ọba gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 35Ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sá à ni èmi lónìí, ǹjẹ́ èmi mọ ìyàtọ̀ nínú rere àti búburú? Ǹjẹ́ ìránṣẹ́ rẹ le mọ adùn ohun tí òun ń jẹ tàbí ohun ti òun ń mu bí? Èmi tún lè mọ adùn ohùn àwọn ọkùnrin tí ń kọrin àti àwọn obìnrin tí ń kọrin bí, ǹjẹ́ nítorí kín ni ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe jẹ́ ìyọnu síbẹ̀ fún olúwa mi ọba. 36Ìránṣẹ́ rẹ yóò sì sin ọba lọ díẹ̀ gòkè odò Jordani; èéṣì ṣe tí ọba yóò fi san ẹ̀san yìí fún mi. 37Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ padà, èmi ó sì kú ní ìlú mi, a ó sì sin mí ní ibojì baba àti ìyá mi. Sì wo Kimhamu ìránṣẹ́ rẹ, yóò bá olúwa mi ọba gòkè; ìwọ ó sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ fún un.” 38Ọba sì dáhùn wí pé, “Kimhamu yóò bá mi gòkè, èmi ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀ fún un; ohunkóhun tí ìwọ bá sì béèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó ṣe é fún ọ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.