Native Bible

2 Samuel 19:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí ìránṣẹ́ rẹ, fún olúwa mi ọba, ṣùgbọ́n bí angẹli Ọlọ́run ni olúwa mi ọba rí, nítorí náà ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ.

2 Samuel 19:27 in English

2 Samuel 19:27 · Berean Standard Bible

and he has slandered your servant to my lord the king. Yet my lord the king is like the angel * of God, so do what is good in your eyes.

Context

25Nígbà tí òun sì wá sí Jerusalẹmu láti pàdé ọba, ọba sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ kò fi bá mi lọ, Mefiboṣeti?” 26Òun sì dáhùn wí pé, “Olúwa mi, ọba, ìránṣẹ́ mi ni ó tàn mí, nítorí ìránṣẹ́ rẹ wí fún un pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi èmi ó gùn ún, èmi ó sì tọ ọba lọ.’ Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ yarọ. 27Ó sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí ìránṣẹ́ rẹ, fún olúwa mi ọba, ṣùgbọ́n bí angẹli Ọlọ́run ni olúwa mi ọba rí, nítorí náà ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ. 28Nítorí pé gbogbo ilé baba mi bí òkú ènìyàn ni wọ́n sá à rí níwájú olúwa mi ọba, ìwọ sì fi ipò fún ìránṣẹ́ rẹ láàrín àwọn tí ó ń jẹun ní ibi oúnjẹ. Nítorí náà àre kín ni èmi ní tí èmi yóò fi máa ké pe ọba síbẹ̀.” 29Ọba sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń sọ ọ̀ràn ara rẹ fún mi èmi sá à ti wí pé, kí ìwọ àti Ṣiba pín ilẹ̀ náà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.