2 Samuẹli 19:25
2 Samuel 19:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí òun sì wá sí Jerusalẹmu láti pàdé ọba, ọba sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ kò fi bá mi lọ, Mefiboṣeti?”
2 Samuel 19:25 in English
2 Samuel 19:25 · Berean Standard Bible
And he came from Jerusalem to meet the king, who asked him, “Mephibosheth, why did you not go with me?”
Context
23Ọba sì wí fún Ṣimei pé, “Ìwọ kì yóò kú!” Ọba sì búra fún un. 24Mefiboṣeti ọmọ Saulu sì sọ̀kalẹ̀ láti wá pàdé ọba, kò wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, kò sí tọ́ irùngbọ̀n rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fọ aṣọ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ọba ti jáde títí ó fi di ọjọ́ tí ó fi padà ní àlàáfíà. 25Nígbà tí òun sì wá sí Jerusalẹmu láti pàdé ọba, ọba sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ kò fi bá mi lọ, Mefiboṣeti?” 26Òun sì dáhùn wí pé, “Olúwa mi, ọba, ìránṣẹ́ mi ni ó tàn mí, nítorí ìránṣẹ́ rẹ wí fún un pé, ‘Di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì fún mi èmi ó gùn ún, èmi ó sì tọ ọba lọ.’ Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ yarọ. 27Ó sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí ìránṣẹ́ rẹ, fún olúwa mi ọba, ṣùgbọ́n bí angẹli Ọlọ́run ni olúwa mi ọba rí, nítorí náà ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.