Native Bible

2 Samuel 13:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya.

2 Samuel 13:31 in English

2 Samuel 13:31 · Berean Standard Bible

Then the king stood up, tore his clothes, and lay down on the ground; and all his servants stood by with their clothes torn.

Context

29Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlùkù gun ìbáaka rẹ̀, wọ́n sì sá. 30Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Dafidi pé, “Absalomu pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn.” 31Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya. 32Jonadabu ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú, nítorí láti ẹnu Absalomu wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀. 33Ǹjẹ́ kí olúwa mi ọba má ṣe fi nǹkan yìí sí ọkàn pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ni o kú, nítorí Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.