2 Samuẹli 13:29
2 Samuel 13:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlùkù gun ìbáaka rẹ̀, wọ́n sì sá.
2 Samuel 13:29 in English
2 Samuel 13:29 · Berean Standard Bible
So Absalom’s young men did to Amnon just as Absalom had ordered. Then all the other sons of the king got up, and each one fled on his mule.
Context
27Absalomu sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Amnoni àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ. 28Absalomu sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Kí ẹ̀yin máa kíyèsi àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Amnoni dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, ‘Kọlu Amnoni,’ kí ẹ sì pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin? Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ.” 29Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlùkù gun ìbáaka rẹ̀, wọ́n sì sá. 30Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Dafidi pé, “Absalomu pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn.” 31Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.