Native Bible

2 Samuel 12:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Natani sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ni ọkùnrin náà. Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, ‘Èmi fi ọ́ jẹ ọba lórí Israẹli, èmi sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Saulu.

2 Samuel 12:7 in English

2 Samuel 12:7 · Berean Standard Bible

Then Nathan said to David, “You are that man! This is what the LORD, the God of Israel, says: ‘I anointed you king over Israel, and I delivered you from the hand of Saul.

Context

5Ìbínú Dafidi sì ru gidigidi sí ọkùnrin náà; ó sì wí fún Natani pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkan yìí, kíkú ni yóò kú. 6Òun yóò sì san àgùntàn náà padà ní mẹ́rin mẹ́rin, nítorí tí ó ṣe nǹkan yìí àti nítorí tí kò ní àánú.” 7Natani sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ni ọkùnrin náà. Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, ‘Èmi fi ọ́ jẹ ọba lórí Israẹli, èmi sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Saulu. 8Èmi sì fi ilé olúwa rẹ fún ọ, àti àwọn obìnrin olúwa rẹ sí àyà rẹ, èmi sì fi ìdílé Israẹli àti ti Juda fún ọ; tí àwọn wọ̀nyí bá sì kéré jù fún ọ èmi ìbá sì fún ọ sí i jù bẹ́ẹ̀ lọ. 9Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Uriah ará Hiti, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ammoni pa á.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.