2 Samuẹli 12:10
2 Samuel 12:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ nítorí náà idà kì yóò kúrò ní ilé rẹ títí láé; nítorí pé ìwọ gàn mí, ìwọ sì mú aya Uriah ará Hiti láti ṣe aya rẹ.’
2 Samuel 12:10 in English
2 Samuel 12:10 · Berean Standard Bible
Now, therefore, the sword will never depart from your house, because you have despised Me and have taken the wife of Uriah the Hittite to be your own.’
Context
8Èmi sì fi ilé olúwa rẹ fún ọ, àti àwọn obìnrin olúwa rẹ sí àyà rẹ, èmi sì fi ìdílé Israẹli àti ti Juda fún ọ; tí àwọn wọ̀nyí bá sì kéré jù fún ọ èmi ìbá sì fún ọ sí i jù bẹ́ẹ̀ lọ. 9Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Uriah ará Hiti, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ammoni pa á. 10Ǹjẹ́ nítorí náà idà kì yóò kúrò ní ilé rẹ títí láé; nítorí pé ìwọ gàn mí, ìwọ sì mú aya Uriah ará Hiti láti ṣe aya rẹ.’ 11“Báyìí ni Olúwa wí, kíyèsi i, ‘Èmi ó jẹ́ kí ibi kí ó dìde sí ọ láti inú ilé rẹ wá, èmi ó sì gba àwọn obìnrin rẹ lójú rẹ, èmi ó sì fi wọ́n fún aládùúgbò rẹ, òun ó sì bá àwọn obìnrin rẹ sùn níwájú òòrùn yìí. 12Àti pé ìwọ ṣe é ní ìkọ̀kọ̀, ṣùgbọ́n èmi ó ṣe nǹkan yìí níwájú gbogbo Israẹli, àti níwájú òòrùn.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.