Native Bible

2 Samuel 11:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn tafàtafà sì ta sí ìránṣẹ́ rẹ láti orí odi wá, díẹ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́ ọba sì kú, ìránṣẹ́ rẹ̀ Uriah ará Hiti sì kú pẹ̀lú.”

2 Samuel 11:24 in English

2 Samuel 11:24 · Berean Standard Bible

Then the archers shot at your servants from the wall, and some of the king’s servants were killed. And your servant Uriah the Hittite is dead as well.”

Context

22Ìránṣẹ́ náà sì lọ, ó sì wá, ó sì jẹ́ gbogbo iṣẹ́ tí Joabu rán an fún Dafidi. 23Ìránṣẹ́ náà sì wí fún Dafidi pé, “Nítòótọ́ àwọn ọkùnrin náà lágbára jù wá lọ, wọ́n sì jáde tọ̀ wá wá ní pápá, àwa sì tẹ̀lé wọn títí wọ́n fi dé ẹ̀yìn odi. 24Àwọn tafàtafà sì ta sí ìránṣẹ́ rẹ láti orí odi wá, díẹ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́ ọba sì kú, ìránṣẹ́ rẹ̀ Uriah ará Hiti sì kú pẹ̀lú.” 25Dafidi sì wí fún ìránṣẹ́ náà pé, “Báyìí ni ìwọ yóò wí fún Joabu pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí nǹkan yìí burú ní ojú rẹ, nítorí pé idà a máa pa lọ́tùn ún lósì, mú ìjà rẹ le sí ìlú náà, kí o sì bì í ṣubú.’ Kí ìwọ sì mú un lọ́kàn le.” 26Nígbà tí aya Uriah sì gbọ́ pé Uriah ọkọ rẹ̀ kú, ó sì ṣọ̀fọ̀ nítorí ọkọ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.