2 Peteru 2:12
2 Peter 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí, bí ẹranko igbó tí kò ní èrò, ẹranko sá á tí a dá láti máa mú pa, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nínú ọ̀rọ̀ tí kò yé wọn, a ó pa wọn run pátápátá nínú ìbàjẹ́ ara wọn.
2 Peter 2:12 in English
2 Peter 2:12 · Berean Standard Bible
These men are like irrational animals, creatures of instinct, born to be captured and destroyed. They blaspheme in matters they do not understand, and like such creatures, they too will be destroyed.
Context
10Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè.
Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo. 11Bẹ́ẹ̀ ni àwọn angẹli bí wọ́n ti pọ̀ ní agbára àti ipá tó o nì, wọn kò dá wọ́n lẹ́jọ́ ẹ̀gàn níwájú Olúwa. 12Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí, bí ẹranko igbó tí kò ní èrò, ẹranko sá á tí a dá láti máa mú pa, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nínú ọ̀rọ̀ tí kò yé wọn, a ó pa wọn run pátápátá nínú ìbàjẹ́ ara wọn. 13Wọn yóò gba ibi padà bí ibi tí wọ́n ti ṣe. Òye ìgbafẹ́ tí wọ́n ní láti máa jẹ adùn ayé. Wọ́n jẹ́ àbàwọ́n àti àbùkù, wọ́n ń jayé nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá ń jẹ àsè pẹ̀lú yín. 14Ojú wọn kún fún panṣágà, wọn kò sì dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá; wọ́n ń tan àwọn tí ọkàn kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ jẹ; àwọn tí wọ́n ní ọkàn tí ó ti yege nínú wọ̀bìà, ọmọ ègún ni wọ́n.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.