Native Bible

2 Peter 2:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè. Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo.

2 Peter 2:10 in English

2 Peter 2:10 · Berean Standard Bible

Such punishment is specially reserved for those who indulge the corrupt desires of the flesh and despise authority. Bold and self-willed, they are unafraid to slander glorious beings.*

Context

8(nítorí ọkùnrin olóòtítọ́ náà bí ó ti ń gbé àárín wọn, tí ó ń rí, tí ó sì ń gbọ́, lójoojúmọ́ ni ìwà búburú wọn ń bá ọkàn òtítọ́ rẹ̀ jẹ́). 9Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Olúwa mọ bí a tí ń yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdánwò àti bí a ti ń pa àwọn aláìṣòótọ́ mo fún ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí wọn yóò tẹ̀síwájú nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 10Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè. Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo. 11Bẹ́ẹ̀ ni àwọn angẹli bí wọ́n ti pọ̀ ní agbára àti ipá tó o nì, wọn kò dá wọ́n lẹ́jọ́ ẹ̀gàn níwájú Olúwa. 12Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí, bí ẹranko igbó tí kò ní èrò, ẹranko sá á tí a dá láti máa mú pa, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nínú ọ̀rọ̀ tí kò yé wọn, a ó pa wọn run pátápátá nínú ìbàjẹ́ ara wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.