Native Bible

2 Kings 8:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gẹ́gẹ́ bí fún iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Jehoramu, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda?

2 Kings 8:23 in English

2 Kings 8:23 · Berean Standard Bible

As for the rest of the acts of Jehoram, along with all his accomplishments, are they not written in the book of the Chronicles of the Kings of Judah?

Context

21Bẹ́ẹ̀ ni Jehoramu lọ sí Sairi pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Àwọn ará Edomu sì yí i ká àti kẹ̀kẹ́ àwọn olórí wọn, ṣùgbọ́n ó dìde dúró ní òru; àwọn ogun rẹ̀ síbẹ̀síbẹ̀, sá padà lọ ilé. 22Títí ó fi di òní, Edomu wà nínú ọ̀tẹ̀ lórí Juda, Libina ṣọ̀tẹ̀ ní àkókò kan náà. 23Gẹ́gẹ́ bí fún iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Jehoramu, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? 24Jehoramu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú Dafidi, Ahasiah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 25Ní ọdún méjìlá Joramu ọmọkùnrin Ahabu ọba Israẹli, Ahasiah ọmọkùnrin Jehoramu ọba Juda bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.