Native Bible

2 Kings 8:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Eliṣa da á lóhùn pé, “Lọ kí o lọ sọ fún un pé, ‘Ìwo ìbá sàn nítòótọ́’; ṣùgbọ́n Olúwa ti fihàn mí pé nítòótọ́ òun yóò kùú.”

2 Kings 8:10 in English

2 Kings 8:10 · Berean Standard Bible

Elisha answered, “Go and tell him, ‘You will surely recover.’ But the LORD * has shown me that in fact he will die.”

Context

8ọba sì wí fún Hasaeli pé, “Mú ọrẹ lọ́wọ́ rẹ, sì lọ pàdé ènìyàn Ọlọ́run. Kí o sì béèrè Olúwa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn yìí?” 9Hasaeli lọ láti pàdé Eliṣa, ó mú lọ pẹ̀lú rẹ̀ ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí ogójì ẹrù ìbákasẹ tí gbogbo ìní tí ó dára jù fún wíwò ti Damasku, ó sì wọlé lọ ó sì dúró níwájú rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọ rẹ Beni-Hadadi ọba Siria rán mi láti béèrè pé, ‘Ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn mi yìí?’ ” 10Eliṣa da á lóhùn pé, “Lọ kí o lọ sọ fún un pé, ‘Ìwo ìbá sàn nítòótọ́’; ṣùgbọ́n Olúwa ti fihàn mí pé nítòótọ́ òun yóò kùú.” 11Ó sì ranjú mọ́ ọn pẹ̀lú àtẹjúmọ́ gidigidi títí tí ojú fi ti Hasaeli. Nígbà náà ènìyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. 12“Kí ni ó dé tí olúwa mi fi ń sọkún?” Hasaeli béèrè. “Nítorí pé èmi mọ ibi tí ìwọ yóò ṣe sí Israẹli,” ó sì dáhùn pé, “Ìwọ yóò fi iná si odi agbára wọn, ìwọ yóò, pa àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú idà, ìwọ yóò kọlù àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, ìwọ ó sì fọ́ wọn túútúú, ìwọ o sì la inú àwọn aboyún wọn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.