Native Bible

2 Kings 6:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nísinsin yìí Eliṣa jókòó ní ilé rẹ̀ àwọn àgbàgbà náà jókòó pẹ̀lú rẹ̀. Ọba sì rán oníṣẹ́ síwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó tó dé ibẹ̀, Eliṣa sọ fún àwọn àgbàgbà pé, “Ṣé ẹ̀yin kò rí bí apànìyàn ti ń rán ẹnìkan láti gé orí mi kúrò? Ẹ wò ó, nígbà tí ìránṣẹ́ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn kí ẹ sì dìímú ṣinṣin ní ẹnu-ọ̀nà, ìró ẹsẹ̀ olúwa rẹ̀ kò ha wà lẹ́yìn rẹ?”

2 Kings 6:32 in English

2 Kings 6:32 · Berean Standard Bible

Now Elisha was sitting in his house, and the elders were sitting with him. The king sent a messenger ahead, but before he arrived, Elisha said to the elders, “Do you see how this murderer has sent someone to cut off my head? Look, when the messenger comes, shut the door to keep him out. Is not the sound of his master’s footsteps behind him?”

Context

30Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ obìnrin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Gẹ́gẹ́ bí ó sì ti ń kọjá lọ sí orí odi, àwọn ènìyàn wò ó níbẹ̀ ní abẹ́, ó ní aṣọ ọ̀fọ̀ ní ara rẹ̀. 31Ó sì wí pé, “Kí Ọlọ́run kí ó fi ìyà jẹ mí, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ dájúdájú, pé orí ọmọkùnrin Eliṣa ọmọ Ṣafati kì ó wà ní ọrùn rẹ̀ ní òní!” 32Nísinsin yìí Eliṣa jókòó ní ilé rẹ̀ àwọn àgbàgbà náà jókòó pẹ̀lú rẹ̀. Ọba sì rán oníṣẹ́ síwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó tó dé ibẹ̀, Eliṣa sọ fún àwọn àgbàgbà pé, “Ṣé ẹ̀yin kò rí bí apànìyàn ti ń rán ẹnìkan láti gé orí mi kúrò? Ẹ wò ó, nígbà tí ìránṣẹ́ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn kí ẹ sì dìímú ṣinṣin ní ẹnu-ọ̀nà, ìró ẹsẹ̀ olúwa rẹ̀ kò ha wà lẹ́yìn rẹ?” 33Nígbà tí ó sì ń sọ̀rọ̀ sí wọn, ìránṣẹ́ náà sọ̀kalẹ̀ wá bá a. Ọba náà sì wí pé, “Ibi yìí láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni. Kí ni ó dé tí èmi yóò fi dúró de Olúwa sí i?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.