Native Bible

2 Kings 6:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ obìnrin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Gẹ́gẹ́ bí ó sì ti ń kọjá lọ sí orí odi, àwọn ènìyàn wò ó níbẹ̀ ní abẹ́, ó ní aṣọ ọ̀fọ̀ ní ara rẹ̀.

2 Kings 6:30 in English

2 Kings 6:30 · Berean Standard Bible

When the king heard the words of the woman, he tore his clothes. And as he passed by on the wall, the people saw the sackcloth under his clothes next to his skin.

Context

28Nígbà náà ọba béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” Obìnrin náà dáhùn pé, “Obìnrin yìí wí fún mi pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ ẹ́ lónìí, ní ọ̀la àwa yóò jẹ ọmọkùnrin tèmi.’ 29Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ọmọkùnrin mi a sì jẹ ẹ́. Ní ọjọ́ kejì mo wí fún un pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ,’ ṣùgbọ́n ó ti gbé e pamọ́.” 30Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ obìnrin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Gẹ́gẹ́ bí ó sì ti ń kọjá lọ sí orí odi, àwọn ènìyàn wò ó níbẹ̀ ní abẹ́, ó ní aṣọ ọ̀fọ̀ ní ara rẹ̀. 31Ó sì wí pé, “Kí Ọlọ́run kí ó fi ìyà jẹ mí, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ dájúdájú, pé orí ọmọkùnrin Eliṣa ọmọ Ṣafati kì ó wà ní ọrùn rẹ̀ ní òní!” 32Nísinsin yìí Eliṣa jókòó ní ilé rẹ̀ àwọn àgbàgbà náà jókòó pẹ̀lú rẹ̀. Ọba sì rán oníṣẹ́ síwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó tó dé ibẹ̀, Eliṣa sọ fún àwọn àgbàgbà pé, “Ṣé ẹ̀yin kò rí bí apànìyàn ti ń rán ẹnìkan láti gé orí mi kúrò? Ẹ wò ó, nígbà tí ìránṣẹ́ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn kí ẹ sì dìímú ṣinṣin ní ẹnu-ọ̀nà, ìró ẹsẹ̀ olúwa rẹ̀ kò ha wà lẹ́yìn rẹ?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.