Native Bible

2 Kings 6:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run dìde ó sì jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, ogun pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ wọn ti yí ìlú náà ká. “Yé è, olúwa mi! Kí ni kí àwa kí ó ṣe?” ìránṣẹ́ náà béèrè.

2 Kings 6:15 in English

2 Kings 6:15 · Berean Standard Bible

When the servant of the man of God got up and went out early in the morning, an army with horses and chariots had surrounded the city. So he asked Elisha, “Oh, my master, what are we to do?”

Context

13Ọba pa á láṣẹ, “Lọ, kí ẹ lọ wo ibi tí ó wà, kí èmi kí ó lè rán ènìyàn láti lọ mú un wá.” Ìròyìn padà wá wí pé, “Ó wà ní Dotani.” 14Nígbà náà ni ó rán àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ àti ogun ńlá tí ó le síbẹ̀. Wọ́n sì lọ ní alẹ́ wọ́n sì yí ìlú náà ká. 15Nígbà tí ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run dìde ó sì jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, ogun pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ wọn ti yí ìlú náà ká. “Yé è, olúwa mi! Kí ni kí àwa kí ó ṣe?” ìránṣẹ́ náà béèrè. 16“Má ṣe bẹ̀rù,” wòlíì náà dáhùn, “Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa, wọ́n pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.” 17Eliṣa sì gbàdúrà, “Olúwa, la ojú rẹ̀ kí ó ba à lè ríran.” Nígbà náà Olúwa la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì wò, ó sì rí òkè ńlá tí ó kún fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ iná gbogbo yí Eliṣa ká.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.