Native Bible

2 Kings 6:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọba pa á láṣẹ, “Lọ, kí ẹ lọ wo ibi tí ó wà, kí èmi kí ó lè rán ènìyàn láti lọ mú un wá.” Ìròyìn padà wá wí pé, “Ó wà ní Dotani.”

2 Kings 6:13 in English

2 Kings 6:13 · Berean Standard Bible

So the king said, “Go and see where he is, that I may send men to capture him.” On receiving the report, “Elisha is in Dothan,”

Context

11Èyí mú ọba Aramu bínú. Ó pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé ìwọ kò ní sọ fún mi èwo nínú wa ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọba Israẹli?” 12Ọ̀kan lára ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí pé, “Kò sí ọ̀kan nínú wa, olúwa ọba mi, ṣùgbọ́n Eliṣa, wòlíì tí ó wà ní Israẹli, sọ fún ọba Israẹli ọ̀rọ̀ gangan tí ó sọ nínú yàrá rẹ̀.” 13Ọba pa á láṣẹ, “Lọ, kí ẹ lọ wo ibi tí ó wà, kí èmi kí ó lè rán ènìyàn láti lọ mú un wá.” Ìròyìn padà wá wí pé, “Ó wà ní Dotani.” 14Nígbà náà ni ó rán àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ àti ogun ńlá tí ó le síbẹ̀. Wọ́n sì lọ ní alẹ́ wọ́n sì yí ìlú náà ká. 15Nígbà tí ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run dìde ó sì jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, ogun pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ wọn ti yí ìlú náà ká. “Yé è, olúwa mi! Kí ni kí àwa kí ó ṣe?” ìránṣẹ́ náà béèrè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.