Native Bible

2 Kings 5:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ọba Israẹli ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí ààyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo ààrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!”

2 Kings 5:7 in English

2 Kings 5:7 · Berean Standard Bible

When the king of Israel read the letter, he tore his clothes and asked, “Am I God, killing and giving life, that this man expects me to cure a leper? Surely you can see that he is seeking a quarrel with me!”

Context

5“Ní gbogbo ọ̀nà, lọ,” ọba Aramu dá a lóhùn pé, “Èmi yóò fi ìwé ránṣẹ́ sí ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni Naamani lọ, ó sì mú pẹ̀lú rẹ̀ tálẹ́ǹtì fàdákà mẹ́wàá, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ìwọ̀n wúrà àti ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá. 6Ìwé tí ó mú lọ sọ́dọ̀ ọba Israẹli kà pé, “Pẹ̀lú ìwé yìí èmi ń rán ìránṣẹ́ mi Naamani sí ọ pé o lè wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.” 7Bí ọba Israẹli ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí ààyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo ààrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!” 8Nígbà tí Eliṣa ènìyàn Ọlọ́run gbọ́ pé ọba Israẹli ti ya aṣọ rẹ̀, ó sì rán iṣẹ́ yìí sí i pé, “Kí ni ó dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Jẹ́ kí ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi. Òun yóò sì mọ̀ pé wòlíì wà ní Israẹli.” 9Bẹ́ẹ̀ ni Naamani sì lọ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀ àti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé Eliṣa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.