2 Ọba 5:4
2 Kings 5:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Naamani lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Israẹli ti sọ.
2 Kings 5:4 in English
2 Kings 5:4 · Berean Standard Bible
And Naaman went and told his master what the girl from the land of Israel had said.
Context
2Nísinsin yìí ẹgbẹgbẹ́ láti Aramu ti jáde lọ láti mú ọmọ obìnrin kékeré kan ní ìgbèkùn láti Israẹli, ó sì sin ìyàwó Naamani. 3Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samaria! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.” 4Naamani lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Israẹli ti sọ. 5“Ní gbogbo ọ̀nà, lọ,” ọba Aramu dá a lóhùn pé, “Èmi yóò fi ìwé ránṣẹ́ sí ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni Naamani lọ, ó sì mú pẹ̀lú rẹ̀ tálẹ́ǹtì fàdákà mẹ́wàá, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ìwọ̀n wúrà àti ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá. 6Ìwé tí ó mú lọ sọ́dọ̀ ọba Israẹli kà pé, “Pẹ̀lú ìwé yìí èmi ń rán ìránṣẹ́ mi Naamani sí ọ pé o lè wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.