2 Ọba 4:12
2 Kings 4:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Gehasi pé, “Pe ará Ṣunemu.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é wá, ó sì dúró níwájú rẹ̀.
2 Kings 4:12 in English
2 Kings 4:12 · Berean Standard Bible
And he said to Gehazi his servant, “Call the Shunammite woman.” And when he had called her, she stood before him,
Context
10Jẹ́ kí a ṣe yàrá kékeré kan sórí ilé kí a sì gbé ibùsùn àti tábìlì oúnjẹ, àga kan àti fìtílà fún un. Nígbà náà ó lè dúró níbẹ̀ ní ìgbàkúgbà tí ó bá wá sọ́dọ̀ wa.” 11Ní ọjọ́ kan nígbà tí Eliṣa wá, ó lọ sí orí òkè ní yàrá rẹ̀ ó sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀. 12Ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Gehasi pé, “Pe ará Ṣunemu.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é wá, ó sì dúró níwájú rẹ̀. 13Eliṣa wí fún un pé, “Wí fún un, ‘Ìwọ ti lọ ṣe gbogbo àníyàn iṣẹ́ ìyìnrere fún wa. Nísinsin yìí kí ni a lè ṣe fún ọ?’ ”
“Ṣé a lè jẹ́ agbẹnusọ fún ọ ní ọ̀dọ̀ ọba tàbí olórí ogun?” 14“Kí ni a lè ṣe fún obìnrin yìí?” Eliṣa béèrè.
Gehasi wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kò ní ọmọ, ọkọ rẹ̀ náà sì tún di arúgbó.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.