2 Ọba 3:22
2 Kings 3:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, oòrùn ti tàn sí orí omi náà sí àwọn ará Moabu ní ìkọjá ọ̀nà, omi náà sì pupa bí ẹ̀jẹ̀.
2 Kings 3:22 in English
2 Kings 3:22 · Berean Standard Bible
When they got up early in the morning, the sun was shining on the water, and it looked as red as blood to the Moabites across the way.
Context
20Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ní àsìkò ẹbọ, níbẹ̀ ni omí sàn láti ọ̀kánkán Edomu! Ilé náà sì kún pẹ̀lú omi. 21Nísinsin yìí gbogbo ará Moabu gbọ́ pé àwọn ọba tí dé láti bá wọn jà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn, ọmọdé àti àgbà tí ó lè ja ogun wọn pè wọ́n sókè wọ́n sì dúró ní etí ilẹ̀. 22Nígbà tí wọ́n dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, oòrùn ti tàn sí orí omi náà sí àwọn ará Moabu ní ìkọjá ọ̀nà, omi náà sì pupa bí ẹ̀jẹ̀. 23“Ẹ̀jẹ̀ ni èyí!” wọ́n wí pé, “Àwọn ọba wọ̀nyí lè ti jà kí wọn sì pa ara wọn ní ìpakúpa. Nísinsin yìí sí àwọn ìkógun Moabu!” 24Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará Moabu dé sí ibùdó ti Israẹli, àwọn ará Israẹli dìde, wọ́n sì kọlù wọ́n títí tí wọ́n fi sálọ. Àwọn ará Israẹli gbógun sí ilẹ̀ náà wọ́n sì pa Moabu run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.