2 Ọba 3:21
2 Kings 3:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nísinsin yìí gbogbo ará Moabu gbọ́ pé àwọn ọba tí dé láti bá wọn jà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn, ọmọdé àti àgbà tí ó lè ja ogun wọn pè wọ́n sókè wọ́n sì dúró ní etí ilẹ̀.
2 Kings 3:21 in English
2 Kings 3:21 · Berean Standard Bible
Now all the Moabites had heard that the kings had come up to fight against them. So all who could bear arms, young and old, were summoned and stationed at the border.
Context
19Ìwọ yóò sì bi gbogbo ìlú olódi àti gbogbo àgbà ìlú ṣubú. Ìwọ yóò sì gé gbogbo igi dáradára ṣubú, dá gbogbo orísun omi dúró, kí o sì pa gbogbo pápá dáradára pẹ̀lú òkúta run.” 20Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ní àsìkò ẹbọ, níbẹ̀ ni omí sàn láti ọ̀kánkán Edomu! Ilé náà sì kún pẹ̀lú omi. 21Nísinsin yìí gbogbo ará Moabu gbọ́ pé àwọn ọba tí dé láti bá wọn jà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn, ọmọdé àti àgbà tí ó lè ja ogun wọn pè wọ́n sókè wọ́n sì dúró ní etí ilẹ̀. 22Nígbà tí wọ́n dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, oòrùn ti tàn sí orí omi náà sí àwọn ará Moabu ní ìkọjá ọ̀nà, omi náà sì pupa bí ẹ̀jẹ̀. 23“Ẹ̀jẹ̀ ni èyí!” wọ́n wí pé, “Àwọn ọba wọ̀nyí lè ti jà kí wọn sì pa ara wọn ní ìpakúpa. Nísinsin yìí sí àwọn ìkógun Moabu!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.