Native Bible

2 Kings 3:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, mú wá fún mi ohun èlò orin olókùn.” Nígbà tí akọrin náà n kọrin, ọwọ́ Olúwa wá sórí Eliṣa.

2 Kings 3:15 in English

2 Kings 3:15 · Berean Standard Bible

But now, bring me a harpist.*” And while the harpist played, the hand of the LORD came upon Elisha

Context

13Eliṣa wí fún ọba Israẹli pé, “Kí ni àwa ní ṣe pẹ̀lú ara wa? Lọ sọ́dọ̀ wòlíì baba rẹ àti wòlíì ti ìyá rẹ.” Ọba Israẹli dá a lóhùn, “Rárá, nítorí Olúwa ni ó pe àwa ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta papọ̀ láti fi wá lé Moabu lọ́wọ́.” 14Eliṣa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pé Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà láyé, ẹni tí mo ń sìn tí èmi kò bá ní ọ̀wọ̀ fún ojú Jehoṣafati ọba Juda, èmi kò ní wò ó tàbí èmi kì bá ti rí ọ. 15Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, mú wá fún mi ohun èlò orin olókùn.” Nígbà tí akọrin náà n kọrin, ọwọ́ Olúwa wá sórí Eliṣa. 16Ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ‘Jẹ́ kí àfonífojì kún fún ọ̀gbun.’ 17Nítorí èyí ni Olúwa wí, o kò ní í rí afẹ́fẹ́ tàbí òjò, bẹ́ẹ̀ ni àfonífojì yìí yóò kún pẹ̀lú omi, àti ìwọ àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹran yóò mu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.