2 Ọba 25:24
2 Kings 25:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gedaliah sì búra láti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ìjòyè ará Babeli,” ó wí pé, “Ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì sin ọba Babeli, yóò sì dára fún un yín.”
2 Kings 25:24 in English
2 Kings 25:24 · Berean Standard Bible
And Gedaliah took an oath before them and their men, assuring them, “Do not be afraid of the servants of the Chaldeans. Live in the land and serve the king of Babylon, and it will be well with you.”
Context
22Nebukadnessari ọba Babeli ó mú Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani, láti jẹ baálẹ̀ lórí àwọn ènìyàn tí ó kù sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda. 23Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Babeli ti yan Gedaliah gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ni Mispa. Iṣmaeli ọmọ Netaniah, Johanani ọmọ Karea, Seraiah ọmọ Tanhumeti ará Netofa, Jaaṣaniah ọmọ ará Maakati, àti àwọn ọkùnrin wọn. 24Gedaliah sì búra láti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ìjòyè ará Babeli,” ó wí pé, “Ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì sin ọba Babeli, yóò sì dára fún un yín.” 25Ní oṣù keje, ni Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ọmọ Eliṣama, nínú irú-ọmọ ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá, ó sì kọlù Gedaliah àti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá ará Juda àti àwọn ará Babeli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Mispa. 26Nítorí èyí, gbogbo àwọn ènìyàn láti ẹni kékeré títí dé ẹni ńlá, àti pẹ̀lú àwọn olórí ogun, sálọ si Ejibiti nítorí ẹ̀rù àwọn ará Babeli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.