2 Ọba 25:22
2 Kings 25:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nebukadnessari ọba Babeli ó mú Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani, láti jẹ baálẹ̀ lórí àwọn ènìyàn tí ó kù sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda.
2 Kings 25:22 in English
2 Kings 25:22 · Berean Standard Bible
Nebuchadnezzar king of Babylon appointed Gedaliah son of Ahikam, the son of Shaphan, over the people he had left behind in the land of Judah.
Context
20Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla. 21Níbẹ̀ ní Ribla, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babeli sì kọlù wọ́n.
Bẹ́ẹ̀ ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. 22Nebukadnessari ọba Babeli ó mú Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani, láti jẹ baálẹ̀ lórí àwọn ènìyàn tí ó kù sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda. 23Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Babeli ti yan Gedaliah gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ni Mispa. Iṣmaeli ọmọ Netaniah, Johanani ọmọ Karea, Seraiah ọmọ Tanhumeti ará Netofa, Jaaṣaniah ọmọ ará Maakati, àti àwọn ọkùnrin wọn. 24Gedaliah sì búra láti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ìjòyè ará Babeli,” ó wí pé, “Ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì sin ọba Babeli, yóò sì dára fún un yín.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.