2 Ọba 24:5
2 Kings 24:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Juda?
2 Kings 24:5 in English
2 Kings 24:5 · Berean Standard Bible
As for the rest of the acts of Jehoiakim, along with all his accomplishments, are they not written in the Book of the Chronicles of the Kings of Judah?
Context
3Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Juda gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Manase àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe. 4Àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí a ta sílẹ̀ nítorí ó ti kún Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí Olúwa kò sì fẹ́ láti dáríjì. 5Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Juda? 6Jehoiakimu sùn pẹ̀lú baba rẹ̀, Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. 7Ọba Ejibiti kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Babeli ti gba gbogbo agbègbè rẹ̀ láti odò Ejibiti lọ sí odò Eufurate.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.