2 Ọba 23:6
2 Kings 23:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó mú ère òrìṣà Aṣerah láti ilé Olúwa sí àfonífojì Kidironi ní ìta Jerusalẹmu, ó sì sun wọ́n níbẹ̀. Ó lọ̀ ọ́ bí àtíkè ó sì fọ́n eruku náà sórí isà òkú àwọn ènìyàn tí ó wọ́pọ̀.
2 Kings 23:6 in English
2 Kings 23:6 · Berean Standard Bible
He brought the Asherah pole from the house of the LORD to the Kidron Valley outside Jerusalem, and there he burned it, ground it to powder, and threw its dust on the graves of the common people.
Context
4Ọba sì pàṣẹ fún Hilkiah olórí àlùfáà àti àwọn, àlùfáà tí ó tẹ̀lé e ní ipò àti àwọn olùṣọ́nà láti yọ kúrò nínú ilé Olúwa gbogbo ohun èlò tí a ṣe fún Baali àti Aṣerah àti gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run. Ó sì sun wọ́n ní ìta Jerusalẹmu ní pápá àfonífojì Kidironi. Ó sì kó eérú wọn jọ sí Beteli. 5Ó sì kúrò pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà tí a yàn láti ọwọ́ ọba Juda láti sun tùràrí ní ibi gíga ti ìlú Juda àti àwọn tí ó yí Jerusalẹmu ká. Àwọn tí ó ń sun tùràrí sí Baali, sí oòrùn àti òṣùpá, sí àwọn àmì ìràwọ̀ àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run. 6Ó mú ère òrìṣà Aṣerah láti ilé Olúwa sí àfonífojì Kidironi ní ìta Jerusalẹmu, ó sì sun wọ́n níbẹ̀. Ó lọ̀ ọ́ bí àtíkè ó sì fọ́n eruku náà sórí isà òkú àwọn ènìyàn tí ó wọ́pọ̀. 7Ó sì wó ibùgbé àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà lulẹ̀. Tí ó wà nínú ilé Olúwa àti ibi tí àwọn obìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun fún òrìṣà Aṣerah. 8Josiah kó gbogbo àwọn àlùfáà láti àwọn ìlú Juda ó sì ba ibi mímọ́ wọ̀n-ọn-nì jẹ́ láti Geba sí Beerṣeba, níbi tí àwọn àlùfáà ti sun tùràrí. Ó wó àwọn ojúbọ lulẹ̀ ní ẹnu ìlẹ̀kùn—ní ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ti Joṣua, baálẹ̀ ìlú ńlá tí ó wà ní apá òsì ẹnu ìlẹ̀kùn ìlú ńlá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.