Native Bible

2 Kings 22:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò mú ibi wá sí ibí àti àwọn ènìyàn rẹ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé tí ọba Juda ti kà.

2 Kings 22:16 in English

2 Kings 22:16 · Berean Standard Bible

that this is what the LORD says: I am about to bring calamity on this place and on its people, according to all the words of the book that the king of Judah has read,

Context

14Hilkiah àlùfáà, Ahikamu àti Akbori Ṣafani pẹ̀lú Asaiah, lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin Hulda láti lọ bá a sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ aya Ṣallumu ọmọ Tikfa ọmọ Harhasi alábojútó ibi ìpa aṣọ mọ́ sí. Ó ń gbé ní Jerusalẹmu ní ìdàkejì. 15Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, Sọ fún ọkùnrin tí ó rán an yín sí mi, 16‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò mú ibi wá sí ibí àti àwọn ènìyàn rẹ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé tí ọba Juda ti kà. 17Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì tún sun tùràrí fún ọlọ́run mìíràn. Wọ́n sì mú mi bínú nípa gbogbo àwọn òrìṣà tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn dá. Ìbínú mi yóò ru sí ibí yìí, kì yóò sì rọlẹ̀.’ 18Sọ fún ọba Juda tí ó rán yín láti béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí nípa ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí ìwọ ti gbọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.