Native Bible

2 Kings 22:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Hilkiah àlùfáà, Ahikamu àti Akbori Ṣafani pẹ̀lú Asaiah, lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin Hulda láti lọ bá a sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ aya Ṣallumu ọmọ Tikfa ọmọ Harhasi alábojútó ibi ìpa aṣọ mọ́ sí. Ó ń gbé ní Jerusalẹmu ní ìdàkejì.

2 Kings 22:14 in English

2 Kings 22:14 · Berean Standard Bible

So Hilkiah the priest, Ahikam, Achbor, Shaphan, and Asaiah went and spoke to Huldah the prophetess, the wife of Shallum son of Tikvah,* the son of Harhas,* the keeper of the wardrobe. She lived in Jerusalem, in the Second District.*

Context

12Ó pa àṣẹ yìí fún Ahikamu àlùfáà, Hilkiah ọmọ Ṣafani, Akbori ọmọ Mikaiah, àti Ṣafani akọ̀wé àti Asaiah ìránṣẹ́ ọba. 13“Lọ, ẹ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún mi àti fún àwọn ènìyàn àti fún gbogbo Juda nípa ohun tí a kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ń jó sí wa nítorí àwọn baba wa kò tẹ̀lé ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí; wọn kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ níbẹ̀ nípa wa.” 14Hilkiah àlùfáà, Ahikamu àti Akbori Ṣafani pẹ̀lú Asaiah, lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin Hulda láti lọ bá a sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ aya Ṣallumu ọmọ Tikfa ọmọ Harhasi alábojútó ibi ìpa aṣọ mọ́ sí. Ó ń gbé ní Jerusalẹmu ní ìdàkejì. 15Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, Sọ fún ọkùnrin tí ó rán an yín sí mi, 16‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò mú ibi wá sí ibí àti àwọn ènìyàn rẹ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé tí ọba Juda ti kà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.