Native Bible

2 Kings 22:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà Ṣafani akọ̀wé sọ fún ọba pé, “Hilkiah àlùfáà ti fún un ní ìwé kan.” Ṣafani kà lára rẹ̀ níwájú ọba.

2 Kings 22:10 in English

2 Kings 22:10 · Berean Standard Bible

Moreover, Shaphan the scribe told the king, “Hilkiah the priest has given me a book.” And Shaphan read it in the presence of the king.

Context

8Hilkiah olórí àlùfáà sọ fún Ṣafani akọ̀wé pé, “Èmi rí ìwé òfin nílé Olúwa.” Ó fi fún Ṣafani, ẹni tí ó kà á. 9Nígbà náà, Ṣafani akọ̀wé lọ sí ọ̀dọ̀ ọba. Ó sì sọ fún un pé, “Àwọn ìjòyè rẹ ti san owó náà tí ó wà nínú ilé Olúwa. Èmi sì ti fi lé ọwọ́ àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ náà àti àwọn alábojútó nílé Olúwa.” 10Nígbà náà Ṣafani akọ̀wé sọ fún ọba pé, “Hilkiah àlùfáà ti fún un ní ìwé kan.” Ṣafani kà lára rẹ̀ níwájú ọba. 11Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya. 12Ó pa àṣẹ yìí fún Ahikamu àlùfáà, Hilkiah ọmọ Ṣafani, Akbori ọmọ Mikaiah, àti Ṣafani akọ̀wé àti Asaiah ìránṣẹ́ ọba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.