2 Ọba 20:17
2 Kings 20:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àkókò náà yóò sì dé nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà ní ààfin àti gbogbo ohun tí baba rẹ̀ ti kó pamọ́ sókè títí di ọjọ́ òní, wọn yí ó gbe lọ sí Babeli, kò sí ohun tí yóò kù, ni Olúwa wí.
2 Kings 20:17 in English
2 Kings 20:17 · Berean Standard Bible
The time will surely come when everything in your palace and all that your fathers have stored up until this day will be carried off to Babylon. Nothing will be left, says the LORD.
Context
15Wòlíì náà béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí ní ààfin rẹ?”
“Wọ́n rí gbogbo nǹkan ní ààfin mi,” Hesekiah wí pé. “Kò sí nǹkan kan lára àwọn ìṣúra tí èmi kò fihàn wọ́n.” 16Nígbà náà Isaiah wí fún Hesekiah pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, 17àkókò náà yóò sì dé nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà ní ààfin àti gbogbo ohun tí baba rẹ̀ ti kó pamọ́ sókè títí di ọjọ́ òní, wọn yí ó gbe lọ sí Babeli, kò sí ohun tí yóò kù, ni Olúwa wí. 18Àti díẹ̀ nínú àwọn ìran rẹ, ẹran-ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀, tí wọn yóò bí fún ọ, ni wọn yóò kó lọ, wọn yóò sì di ìwẹ̀fà ní ààfin ọba Babeli.” 19Hesekiah wí fún Isaiah pé. “Rere ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ sọ.” Nítorí ó rò wí pé, “Kò ha dára àlàáfíà àti òtítọ́ ní ọjọ́ ayé mi?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.