2 Ọba 2:22
2 Kings 2:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Omi náà sì ti dára ni mímu títí di òní, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Eliṣa ti sọ.
2 Kings 2:22 in English
2 Kings 2:22 · Berean Standard Bible
And the waters there have been healthy to this day, according to the word spoken by Elisha.
Context
20Ó sì wí pé, “Mú àwokòtò tuntun fún mi wá, kí o sì mú iyọ̀ sí inú rẹ̀.” Wọ́n sì gbé e wá fún un. 21Nígbà náà ó sì jáde lọ sí ibi orísun omi, ó sì da iyọ̀ sí inú rẹ̀, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi ti wo omi yìí sàn. Kò ní mú ikú wá mọ́ tàbí mú ilẹ̀ náà sá.’ ” 22Omi náà sì ti dára ni mímu títí di òní, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Eliṣa ti sọ. 23Láti ibẹ̀ Eliṣa lọ sókè ní Beteli gẹ́gẹ́ bí ó ti ń rìn lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọ̀dọ́ kan jáde wá láti ìlú náà wọ́n sì fi ṣe ẹlẹ́yà. “Máa lọ sókè ìwọ apárí!” Wọ́n wí pé. “Máa lọ sókè ìwọ apárí!” 24Ó sì yípadà, ó sì wò wọ́n ó sì fi wọ́n bú ní orúkọ Olúwa. Nígbà náà beari méjì sì jáde wá láti inú igbó ó sì lu méjìlélógójì lára àwọn ọ̀dọ́ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.